Ezekiel 13:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nítorí pé ẹ̀ ń fi àrékérekè ba àwọn olódodo lọ́kàn jẹ́, nígbà tí n kò fẹ́ bà wọ́n lọ́kàn jẹ́; ẹ sì ń ṣe onígbọ̀wọ́ àwọn eniyan burúkú kí wọn má baà yipada lọ́nà ibi wọn, kí wọn sì rí ìgbàlà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe eke li ẹnyin fi mu ọkàn awọn olododo kãnu, awọn ẹniti emi kò mu kãnu, ẹnyin si mu ọwọ́ enia buburu le, ki o má ba pada kuro li ọ̀na buburu rẹ̀ nipa ṣiṣe ileri ìye fun u:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé ẹ ti ba ọkàn àwọn olódodo jẹ́ pẹ̀lú irọ́ yín, nígbà tí Èmi kò mú ìbànújẹ́ bá wọn, àti nítorí ẹ̀yin ti mú ọkàn àwọn ènìyàn búburú le, kí wọ́n má baà kúrò nínú ọ̀nà ibi wọn débi tí wọn yóò fi gba ẹ̀mí wọn là,