Ezekiel 13:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, ẹ kò ní ríran èké mọ́, ẹ kò sì ní woṣẹ́ mọ́. N óo gba àwọn eniyan mi lọ́wọ́ yín, nígbà náà, ni ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ẹnyin kì yio ri asan mọ, ẹ kì yio si ma fọ àfọṣẹ, nitoriti emi o gba awọn enia mi kuro li ọwọ́ nyin, ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nítorí èyí, ẹ̀yin kò ní í ríran èké, ẹ̀yin kò sì ní fọ àfọ̀ṣẹ mọ́. Èmi yóò gba àwọn ènìyàn mi lọ́wọ́ yín. Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni OLÚWA.’ ”