Ezekiel 13:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n ń sọ̀rọ̀ èké, wọ́n ń woṣẹ́ irọ́, wọ́n ń wí pé, ‘OLUWA wí báyìí.’ Bẹ́ẹ̀ sì ni OLUWA kò rán wọn níṣẹ́ kankan; sibẹ wọ́n ń retí pé kí OLUWA mú ọ̀rọ̀ wọn ṣẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn ti ri asan ati àfọṣẹ eke, pe, Oluwa wi: bẹ̃ni Oluwa kò rán wọn, nwọn si ti jẹ ki awọn ẹlomiran ni ireti pe, nwọn o fi idí ọ̀rọ wọn mulẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìran àti àfọ̀ṣẹ wọn jẹ́ èké. Wọ́n wí pé, “OLÚWA wí” nígbà tí OLÚWA kò rán wọn, síbẹ̀ wọ́n fẹ́ kí OLÚWA mú ọ̀rọ̀ wọn ṣẹ.