Ezekiel 14:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo ṣe bẹ́ẹ̀, kí ẹ̀yin ọmọ Israẹli má baà ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi mọ́, tabi kí ẹ máa fi ẹ̀ṣẹ̀ sọ ara yín di aláìmọ́. Ṣugbọn kí ẹ lè jẹ́ eniyan mi, kí n sì jẹ́ Ọlọrun yín. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ile Israeli má ba ṣako lọ kuro lọdọ mi mọ, ki nwọn má ba fi gbogbo irekọja wọn bà ara wọn jẹ mọ, ṣugbọn ki nwọn ki o le jẹ enia mi, ki emi si le jẹ Ọlọrun wọn, ni Oluwa Ọlọrun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ilé Ísírẹ́lì má baà sìnà kúrò lọ́dọ̀ mi tàbí kí wọ́n má baà sọra wọn di aláìmọ́ torí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ṣùgbọ́n kí wọ́n le jẹ́ ènìyàn mi, kí Èmi náà sì le jẹ́ Ọlọ́run wọn, ni OLÚWA Ọlọ́run wí.’ ”