Ezekiel 14:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ìwọ ọmọ eniyan, bí orílẹ̀-èdè kan bá ṣẹ̀ mí, tí wọ́n ṣe aiṣootọ, tí mo bá run gbogbo oúnjẹ wọn, tí mo mú kí ìyàn jà ní ilẹ̀ náà, tí mo sì run ati eniyan ati ẹranko inú rẹ̀,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọmọ enia, nigbati ilẹ na ba ṣẹ̀ si mi nipa irekọja buburu, nigbana ni emi o nawọ mi le e, emi o si ṣẹ́ ọpa onjẹ inu rẹ̀, emi o si rán ìyan si i, emi o si ke enia ati ẹranko kuro ninu rẹ̀:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọmọ ènìyàn bí orílẹ̀ èdè kan bá ṣẹ́ mí nípa ìwà àìṣòdodo, èmi yóò nawọ́ mi jáde sí wọn, láti gé ìpèsè oúnjẹ wọn, n ó rán ìyàn sí wọn, èmi yóò sì pa ènìyàn àti ẹranko inú rẹ̀,