Ezekiel 14:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
bí Noa, ati Daniẹli ati Jobu bá tilẹ̀ wà níbẹ̀, bí èmi OLUWA Ọlọrun fi ara mi búra pé, wọn kò ní lè gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin wọn là. Ara wọn nìkan ni wọn yóo lè gbàlà, ilẹ̀ náà yóo sì di ahoro.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi awọn ọkunrin mẹta wọnyi tilẹ wà ninu rẹ̀, Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, nwọn kì yio gbà ọmọkunrin tabi ọmọbinrin là; awọn nikan li a o gbàla, ṣugbọn ilẹ na yio di ahoro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí wà níbẹ̀ bí mo ti wà láàyè ní OLÚWA Ọlọ́run wí, wọn kò lé gba àwọn ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin wọn là, ilẹ̀ náà yóò di ahoro.