Ezekiel 14:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
bí àwọn ọkunrin mẹta náà bá tilẹ̀ wà níbẹ̀, bí èmi OLUWA ti wà láàyè, wọn kò ní lè gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin wọn là. Ara wọn nìkan ni wọn yóo lè gbàlà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi awọn ọkunrin mẹta yi tilẹ wà ninu rẹ̀, Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, nwọn kì yio gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin là, ṣugbọn awọn tikara wọn nikan li a o gbàla.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí àwọn ọkúnrin mẹ́ta yìí tilẹ̀ wà nínú rẹ̀, OLÚWA Ọlọ́run wí pé, Bí mo ti wà, wọn ki yóò gba ọmọkúnrin tàbí ọmọbìnrin là, ṣùgbọ́n àwọn tikara wọn nìkan ni a o gbàlà.