Ezekiel 14:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
bí Noa, Daniẹli ati Jobu bá tilẹ̀ wà níbẹ̀, èmi OLUWA Ọlọrun fi ara mi búra pé, wọn kò ní lè gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin wọn là. Ara wọn nìkan ni wọn yóo lè fi òdodo wọn gbàlà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi Noa, Danieli, ati Jobu tilẹ wà ninu rẹ̀, Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, nwọn kì yio gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin là; kìki ọkàn ara wọn ni awọn o fi ododo wọn gbàla.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
bo tilẹ̀ jẹ́ pé Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù wà nínú rẹ, bí mo ti wà láàyè ni OLÚWA Ọlọ́run wí wọn kò le gba ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin wọn lá. Ara wọn nìkan ni ìwà òdodo wọn lè gbà là.