Ezekiel 14:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Sibẹ bí a bá rí àwọn tí wọ́n yè ninu wọn lọkunrin ati lobinrin, tí wọ́n bá wá sọ́dọ̀ rẹ, tí o rí ìwà ati ìṣe wọn, o óo gbà pé mo jàre ní ti ibi tí mo jẹ́ kí ó ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn kiye si i, ninu rẹ̀ li a o kù awọn ti a o yọ silẹ, ti a o mu jade wá, ati ọmọkunrin, ati ọmọbinrin, kiye si i, nwọn o jade tọ̀ nyin wá, ẹnyin o si ri ọ̀na wọn ati iṣe wọn, a o si tù nyin ninu niti ibi ti emi ti mu wá sori Jerusalemu, ani niti gbogbo ohun ti mo ti mu wá sori rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Síbẹ̀, yóò ṣẹ́kù àwọn díẹ̀-àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin tí a ó kó jáde nínú rẹ̀. Wọn yóò wá bá yin, ẹ ó rí ìwà àti ìṣe wọn, nígbà náà ni ẹ ó rí ìtùnú nípa àjálù tí mo mú wá sórí Jérúsálẹ́mù—àní gbogbo àjálù ní mo ti mú wá sórí rẹ̀.