Ezekiel 14:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn yóo jẹ́ ìtùnú fún ọ nígbà tí o bá rí ìwà ati ìṣe wọn, O óo sì mọ̀ pé bí kò bá nídìí, n kò ní ṣe gbogbo ohun tí mo ṣe sí wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si tù nyin ninu, nigbati ẹnyin ba ri ọ̀na wọn ati iṣe wọn: ẹnyin o si mọ̀ pe emi kò ṣe gbogbo ohun ti mo ti ṣe ninu rẹ̀ li ainidi, ni Oluwa Ọlọrun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ẹ bá rí ìwà àti ìṣe wọn, a ó tù yín nínú, nítorí pé ẹ ó mọ̀ pé n kò ṣe nǹkan kan láì nídìí, ni OLÚWA Ọlọ́run wí.”