Ezekiel 14:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn ọkunrin wọnyi kó oriṣa wọn lé ọkàn, wọ́n sì gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ń múni kọsẹ̀ siwaju wọn. Ṣé wọ́n rò pé n óo dá wọn lóhùn tí wọ́n bá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọmọ enia, awọn ọkunrin wọnyi ti gbe oriṣa wọn si ọkàn wọn, nwọn si fi ohun ìdigbolu aiṣedede wọn siwaju wọn: emi o ha jẹ ki nwọn bere lọwọ mi rara bi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọmọ ènìyàn, àwọn ọkùnrin wọnyìí ti gbé òrìṣà kalẹ̀ sínú ọkàn wọn, wọ́n sì gbé àwọn ohun tó lè mú wọn ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ síwájú wọn. Ṣé ó tún yẹ kí n gbà wọ́n láàyè láti wádìí lọ́dọ̀ mi rárá bi? Nítorí náà, sọ fún wọn pé: