Ezekiel 14:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nítorí náà, sọ fún wọn pé, èmi OLUWA Ọlọrun ní ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli tí ó bá kó oriṣa rẹ̀ lé ọkàn tí ó gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ń múni kọsẹ̀ siwaju rẹ̀, tí ó wá tọ wolii wá, èmi OLUWA fúnra mi ni n óo dá a lóhùn gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ oriṣa rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina sọ fun wọn, ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; olukuluku ọkunrin ile Israeli ti o gbe oriṣa rẹ̀ si ọkàn rẹ̀, ti o si fi ohun ìdugbolu aiṣedẽde rẹ̀ siwaju rẹ̀, ti o si wá sọdọ woli; emi Oluwa yio dá ẹniti o wá lohùn gẹgẹ bi ọpọlọpọ oriṣa rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
‘Báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: Bí ẹnikẹ́ni ní ilé Ísírẹ́lì tó ó gbé òrìṣà sí ọkàn wọn, tó tún gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ ṣíwájú rẹ̀, bá wá sọ́dọ̀ wòlíì, Èmi OLÚWA fúnra mi ni n ó dá a lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà ìbọ̀rìṣà rẹ.