Ezekiel 14:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nítorí pé bí ẹnikẹ́ni ninu ẹ̀yin ọmọ Israẹli tabi ninu àwọn àlejò tí wọ́n wọ̀ ní ilẹ̀ Israẹli bá ya ara rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ó Kó oriṣa rẹ̀ lé ọkàn, tí ó sì gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ń múni kọsẹ̀ ka iwájú rẹ̀, tí ó wá tọ wolii lọ láti wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ ní orúkọ mi, èmi OLUWA fúnra mi ni n óo dá a lóhùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori olukuluku ninu ile Israeli, tabi ninu alejo ti o ṣe atipo ni Israeli, ti o yà ara rẹ̀ kuro lọdọ mi, ti o si gbe oriṣa rẹ̀ si ọkàn rẹ̀, ti o si fi ohun ìdugbolu aiṣedẽde rẹ̀ siwaju rẹ̀, ti o si tọ̀ wolĩ kan wá lati bere lọwọ rẹ̀ niti emi: Emi Oluwa yio da a lohùn tikalami:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Bí ẹnikẹ́ni ní ilé Ísírẹ́lì tàbí àlejò tó ń gbé ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, bá ya ara rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi, tó gbé òrìṣà rẹ̀ sọ́kàn rẹ̀, tó tún gbé ohun tó ń mú ni ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ ṣíwájú rẹ, lẹ́yìn èyí tó tún lọ sọ́dọ̀ wòlíì láti béèrè nǹkan lọ́wọ́ mi! Èmi OLÚWA fúnra ara mi ní ń o dá a lóhùn.