Ezekiel 14:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo dójú lé olúwarẹ̀, n óo fi ṣe ẹni àríkọ́gbọ́n ati àmúpòwe. N óo pa á run láàrin àwọn eniyan mi; ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si dojukọ ọkunrin na, emi o si fi i ṣe àmi ati owe, emi o si ké e kuro lãrin awọn enia mi; ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
N ó lodi si írú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ lọ́nà òdì, n ó sì sọ ọ́ di àánú àti òwe. Èmi yóò sì gé e kúrò láàrin àwọn ènìyàn mi. Nígbà náà, ẹ ó mọ̀ pé èmi ni OLÚWA.