Ezekiel 14:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Bí wolii kan bá jẹ́ kí á ṣi òun lọ́nà, tí ó sì sọ̀rọ̀, a jẹ́ pé èmi OLUWA ni mo jẹ́ kí wolii náà ṣìnà, N óo na ọwọ́ ìyà sí i, n óo sì pa á run kúrò láàrin àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi a ba si tan wolĩ na jẹ nigbati o sọ ohun kan, Emi Oluwa ni mo ti tan wolĩ na jẹ, emi o si nawọ mi le e, emi o si run u kuro lãrin Israeli enia mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Bí wọ́n bá sì tan wòlíì náà láti sọtẹ́lẹ̀, Èmi OLÚWA ló tan wòlíì náà, Èmi yóò nawọ́ sí i, èmi yóò sì pa á run kúrò láàrin àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì.