Ezekiel 15:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Iná ni wọ́n ń fi í dá, nígbà tí iná bá jó o lórí, tí ó jó o nídìí, tí ó sì sọ ààrin rẹ̀ di èédú, ṣé ó tún ṣe é fi ṣe ohunkohun?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, a jù u sinu iná bi igi, iná si jo ipẹkun rẹ̀ mejeji, ãrin rẹ̀ si jona. O ha yẹ fun iṣẹkiṣẹ bi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn èyí, ṣe a jù ú sínú iná gẹ́gẹ́ bí epo ìdáná, gbogbo igun rẹ̀ jóná pẹ̀lú àárin rẹ, ṣé o wà le wúlò fún nǹkan kan mọ́?