Ezekiel 15:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo dójú lé wọn, bí wọn tilẹ̀ yọ jáde ninu iná, sibẹsibẹ iná ni yóo jó wọn. Nígbà tí mo bá dójú lé wọn, ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si doju mi kọ wọn, nwọn o jade kuro ninu iná kan, iná miran yio si jo wọn, ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati mo ba dojukọ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò dojúkọ wọ́n. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ti jáde kúrò nínú iná kan síbẹ̀ iná mìíràn yóò pàpà jó wọn. Nígbà tí mo bá sì dojúkọ wọ́n, ẹ ó sì mọ̀ pé Èmi ni OLÚWA.