Ezekiel 16:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ ni mo fi wúrà ati fadaka ṣe ọ̀ṣọ́ sí ọ lára. Aṣọ funfun ati siliki tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára ni mo dá fún ọ. Ò ń jẹ burẹdi tí ó dùn, tí wọ́n fi ìyẹ̀fun tí ó kúnná ṣe, ò ń lá oyin ati òróró; o dàgbà, o sì di arẹwà, o dàbí Ọbabinrin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi ni a fi wura ati fadaka ṣe ọ lọṣọ; aṣọ rẹ si jẹ ọgbọ̀ daradara, ati ṣẹ́dà, ati aṣọ oniṣẹ-ọnà; iwọ jẹ iyẹfun daradara ati oyin, ati ororo: iwọ si ni ẹwà gidigidi, iwọ si gbilẹ di ijọba kan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni mo ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú wúrà àti fàdákà; tí aṣọ rẹ jẹ́ funfun lẹlẹ, olówó iyebíye àti aṣọ tí a ṣiṣẹ́ ọnà sí. Ìyẹ̀fun kíkúnná, oyin àti òróró ni oúnjẹ rẹ. O di arẹwà títí o fi dé ipò ayaba.