Ezekiel 16:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ náà ni oúnjẹ tí mo fún ọ. Mo fún ọ ní ìyẹ̀fun tí ó kúnná, ati òróró, ati oyin pé kí o máa jẹ, ṣugbọn o fi rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Onjẹ mi pẹlu ti mo ti fun ọ, iyẹfun daradara, ati ororo, ati oyin, ti mo fi bọ́ ọ, iwọ tilẹ gbe e kalẹ niwaju wọn fun õrùn didùn: bayi li o si ri, ni Oluwa Ọlọrun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
O tún gbé oúnjẹ tí mo fún ọ-ìyẹ̀fún dáradára, òróró àti oyin-fún wọn gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun olóòórùn dídùn; ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyìí, ni OLÚWA Ọlọ́run wí.