Ezekiel 16:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ò ń ṣe àgbèrè ati gbogbo nǹkan ìríra rẹ, o kò ranti ìgbà èwe rẹ, nígbà tí o wà ní ìhòòhò goloto, tí ò ń ta ẹsẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀!”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ni gbogbo ohun irira rẹ, ati panṣaga rẹ, iwọ kò ranti ọjọ ewe rẹ, nigbati iwọ wà nihoho ti o si wà goloto, ti a si bà ọ jẹ ninu ẹjẹ rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nínú gbogbo iṣẹ́ ìríra àti ìwà àgbérè rẹ, o kò rántí ìgbà èwe rẹ, nígbà tó o wà ní ìhòòhò, tó ń jàgùdù nínú ẹ̀jẹ̀.