Ezekiel 16:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ọwọ́ mi wá tẹ̀ ọ́, mo mú ọ kúrò ninu ẹ̀tọ́ rẹ. Mo jẹ́ kí àwọn ọ̀tá rẹ fi ìwọ̀ra gba ohun ìní rẹ, àwọn ará Filistini tí ìwà burúkú rẹ ń tì lójú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiye si i, emi si ti nawọ mi le ọ lori, mo si ti bu onjẹ rẹ kù, mo si fi ọ fun ifẹ awọn ti o korira rẹ, awọn ọmọbinrin Filistia, ti ìwa ifẹkufẹ rẹ tì loju.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà ni mo fi na ọwọ mi lòdì sí ọ, mo ge ilé rẹ kúrú; èmi yóò sì mú ìfẹ́ àwọn to korìíra rẹ ṣẹ́ lé ọ lórí, àwọn ọmọbìnrin Fílístínì ti ìwàkiwà rẹ̀ jẹ ìyàlẹ́nu fún,