Ezekiel 16:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“O bá àwọn ará Asiria ṣe àgbèrè ẹ̀sìn pẹlu, nítorí pé o kò ní ìtẹ́lọ́rùn sibẹ, lẹ́yìn gbogbo àgbèrè tí o ṣe pẹlu wọn, o kò ní ìtẹ́lọ́rùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ ti ba awọn ara Assiria ṣe panṣaga pẹlu, nitori iwọ kò ni itẹlọrun; nitotọ, iwọ ti ba wọn ṣe panṣaga, sibẹsibẹ kò si le tẹ́ ọ lọrùn,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí àìnítẹ́lọ́rùn rẹ o ṣàgbérè pẹ̀lú ara Ásíríà; síbẹ̀ náà, o kò tún ní ìtẹ́lọ́rùn.