Ezekiel 16:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọkunrin níí máa ń fún àwọn aṣẹ́wó ní ẹ̀bùn, ṣugbọn ní tìrẹ, ìwọ ni ò ń fún àwọn olólùfẹ́ rẹ lẹ́bùn. O fi ń tù wọ́n lójú, kí wọ́n lè máa wá bá ọ ṣe àgbèrè láti ibi gbogbo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn nfi ẹbùn fun gbogbo awọn panṣaga, ṣugbọn iwọ fi ẹbùn rẹ fun gbogbo awọn olufẹ rẹ, iwọ si ta wọn lọrẹ, ki nwọn le tọ̀ ọ wá ni ihà gbogbo fun panṣaga rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọkùnrin máa ń sanwó fún àwọn aṣẹwó ni ṣùgbọ́n ìwọ lo tún ń sanwó fun wọn, tí ó tún ń fún àwọn olólùfẹ́ rẹ lẹ́bùn àti owó ẹ̀yìn kí wọn bá à le máa wá ọ wá láti gbogbo agbègbè fún àgbèrè ṣíṣe.