Ezekiel 16:34 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àgbèrè tìrẹ yàtọ̀ sí ti àwọn aṣẹ́wó yòókù, kò sí ẹni tí ń wá ọ láti bá ọ ṣe àgbèrè; ìwọ ni ò ń fún ọkunrin ní ẹ̀bùn dípò kí wọ́n fún ọ! Èyí ni àgbèrè tìrẹ fi yàtọ̀ sí ti àwọn ẹlòmíràn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eyiti o yatọ si ti awọn obinrin miran si mbẹ ninu rẹ, ninu panṣaga rẹ, ti ẹnikan kò tẹ̀le ọ lati ṣe panṣaga: ati nitipe iwọ ntọrẹ, ti a kò si tọrẹ fun ọ nitorina iwọ yatọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nínú àgbèrè rẹ ìwọ yàtọ̀ sí àwọn alágbèrè obìnrin yòókù; kò sí ẹni tó ń wá ọ fún àgbèrè. Ìwọ ló ń sánwó: nígbà tí wọn yóò sanwó fún ọ, ìdákejì ni ọ́; nítorí pé ìwọ ló ń sanwo bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò rí gbà.