Ezekiel 16:36 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun ní, “Ìwà ìtìjú rẹ ti hàn sí gbangba, o bọ́ra sí ìhòòhò níta, nígbà tí ò ń bá àwọn olólùfẹ́ rẹ ṣe àgbèrè, tí ò ń bọ àwọn oriṣa rẹ, o sì pa àwọn ọmọ rẹ, o fi wọ́n rúbọ sí àwọn oriṣa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Nitoriti a dà ẹgbin rẹ jade, ti a si ri ihoho rẹ nipa panṣaga rẹ pẹlu awọn olufẹ rẹ, ati pẹlu gbogbo oriṣa irira rẹ, ati nipa ẹjẹ awọn ọmọ rẹ, ti iwọ fi fun wọn:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: Nítorí pé ìwọ tú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ jáde, ìwọ sì fi ìhòòhò rẹ hàn, nípa ṣíṣe àgbèrè pẹ̀lú àwọn olólùfẹ̀ẹ̀ rẹ, àti nítorí gbogbo ère tí o fi ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ rẹ ṣe ìrúbọ fún,