Ezekiel 16:37 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wò ó! N óo kó gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ, tí inú rẹ dùn sí jọ, ati àwọn tí o fẹ́ràn ati àwọn tí o kórìíra, ni n óo kó wá láti dojú kọ ọ́ ní gbogbo ọ̀nà. N óo tú ọ sí ìhòòhò lójú wọn, kí wọ́n lè rí ìhòòhò rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si kiye si i, Emi o kó gbogbo awọn olufẹ rẹ jọ, awọn ẹniti iwọ ti ba jaiye, ati gbogbo awọn ti iwọ ti fẹ, pẹlu gbogbo awọn ti iwọ ti korira; ani emi o gbá wọn jọ kakiri si ọ, emi o si fi ihoho rẹ hàn wọn, ki nwọn ki o le ri gbogbo ihoho rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nítorí náà, Èmi yóò ṣa gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ jọ, pẹ̀lú gbogbo àwọn ti ẹ jọ ṣe fàájì, àwọn tí ìwọ fẹ́ àti àwọn tí ìwọ korìíra. Èmi yóò ṣa gbogbo wọn káàkiri, láti mú wọn lòdì sí ọ, èmi yóò sí aṣọ rẹ, níwájú wọn, wọn yóò sì rí ìhòòhò rẹ.