Ezekiel 16:39 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo fi ọ́ lé àwọn olólùfẹ́ rẹ lọ́wọ́, wọn óo wó ilé oriṣa ati ibi ìrúbọ rẹ palẹ̀. Wọn óo tú aṣọ rẹ, wọn óo gba àwọn ohun ọ̀ṣọ́ rẹ, wọn yóo sì fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòòhò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si fi ọ le wọn lọwọ pẹlu, nwọn o si wo ibi giga rẹ, nwọn o si wo ibi giga rẹ palẹ: nwọn o si bọ aṣọ rẹ pẹlu, nwọn o si gbà ohun ọṣọ rẹ didara, nwọn o si fi ọ silẹ ni ihoho, ati ni goloto.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni èmi yóò fà ọ lé àwọn olólùfẹ́ rẹ lọ́wọ́, wọn yóò sì wó gbogbo òkìtì rẹ pẹ̀lú àwọn ojúbọ rẹ palẹ̀. Wọn yóò tú aṣọ kúrò lára rẹ̀, gbogbo ọ̀ṣọ́ rẹ ni wọn yóò gbà, wọn yóò sì fi ọ sílẹ̀ ní ìhòòhò àti ààbò.