Ezekiel 16:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí wọn ṣe bí ọ nìyí: nígbà tí wọ́n bí ọ, wọn kò dá ìwọ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi omi wẹ̀ ọ́. Wọn kò fi iyọ̀ pa ọ́ lára, wọn kò sì fi aṣọ wé ọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati niti ìbi rẹ, a kò da ọ ni iwọ́ ni ijọ ti a bi ọ, bẹ̃ni a kò wẹ̀ ọ ninu omi lati mu ọ mọ́, a kò fi iyọ̀ pa ọ lara rara, bẹ̃ni a kò fi ọja wé ọ rara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ tí a bí ọ, a kò gé okùn ìwọ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì fomi wẹ̀ ọ́ láti mú kí o mọ́, tàbí ká fiyọ̀ pa ọ́ lára tàbí ká fi aṣọ wé ọ.