Ezekiel 16:41 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọn óo dáná sun àwọn ilé rẹ, wọn óo sì ṣe ìdájọ́ fún ọ lójú àwọn obinrin pupọ. N kò ní jẹ́ kí o ṣe àgbèrè mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní jẹ́ kí o fún àwọn olólùfẹ́ rẹ ní ẹ̀bùn mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si fi iná kun gbogbo ile rẹ; nwọn o si mu idajọ ṣẹ si ọ lara niwaju obinrin pupọ; emi o si jẹ ki o fi panṣaga rẹ mọ, iwọ pẹlu kì yio si funni ni ọ̀ya mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò jo gbogbo ilé rẹ palẹ̀ wọn yóò sì fi ìyà jẹ ọ́ ní ojú àwọn obìnrin. Èmi yóò fi òpin sí àgbèrè ṣíṣe rẹ. Ìwọ kò sì ní san owó fún àwọn olólùfẹ́ rẹ mọ́.