Ezekiel 16:43 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé o kò ranti ìgbà èwe rẹ, ṣugbọn o mú mi bínú nítorí nǹkan wọnyi. Nítorí náà n óo da èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ lé ọ lórí. Ṣé o kò tún ti fi ìwà ainitiju kún ìwà ìríra rẹ?” OLUWA Ọlọrun ni ó sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe iwọ kò ranti ọjọ ewe rẹ, ṣugbọn o si mu mi kanra ninu gbogbo nkan wọnyi; si kiye si i, nitorina emi pẹlu o san ẹsan ọ̀na rẹ si ọ lori, ni Oluwa Ọlọrun wi: iwọ kì yio si ṣe ifẹkufẹ yi lori gbogbo ohun irira rẹ mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Nítorí pé o kò rántí ọjọ́ èwe rẹ ṣùgbọ́n ìwọ ń rí mi fín pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ó dájú pé Èmi yóò mú gbogbo ohun tí ìwọ ti ṣe wa sórí rẹ, ni OLÚWA Ọlọ́run wí, Ìwọ kì yóò sì ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yìí ni orí gbogbo ohun ìríra rẹ?