Ezekiel 16:45 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọmọ bíbí inú ìyá rẹ ni ọ́, tí kò bìkítà fún ọkọ ati àwọn ọmọ rẹ̀. Ìwà kan náà ni ó wà lọ́wọ́ ìwọ ati àwọn arabinrin rẹ, àwọn náà kò ka ọkọ ati àwọn ọmọ wọn sí. Ará Hiti ni ìyá rẹ, ará Amori sì ni baba rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ ni ọmọ iyá rẹ ti o kọ̀ ọkọ rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀; iwọ ni arabinrin awọn arabinrin rẹ, ti o kọ̀ awọn ọkọ wọn ati awọn ọmọ wọn: ará Hiti ni iyá rẹ, ará Amori si ni baba rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọmọ ìyà rẹ ni ọ lóòtọ́, to korìíra ọkọ rẹ àti àwọn ọmọ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ara ilé àwọn arábìnrin rẹ ni ọ nitootọ, àwọn to n korìíra ọkọ wọn sílẹ̀, tó tún ń korìíra àwọn ọmọ. Ará Híítì ni ìyá rẹ, baba rẹ si jẹ́ ara Ámórì.