Ezekiel 16:47 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Títẹ̀lé ìṣe wọn nìkan kò tẹ́ ọ lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni ṣíṣe ohun ìríra bíi tiwọn kò tó ọ. Láìpẹ́ ọjọ́, ìwà tìrẹ gan-an yóo burú ju tiwọn lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn iwọ kò rin ni ọ̀na wọn, iwọ kò si ṣe gẹgẹ bi irira wọn: ṣugbọn, bi ẹnipe ohun kekere ni eyini, iwọ bajẹ jù wọn lọ ni gbogbo ọ̀na rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kì í sẹ pé ìwọ rìn ni ọ̀nà wọn nìkan, tàbí ṣe àfiwé ìwà irira wọn ṣùgbọ́n ní àárin àkókò kúkúrú díẹ̀, ìwọ bàjẹ́ jù wọ́n lọ