Ezekiel 16:49 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ohun tí Sodomu arabinrin rẹ ṣe tí kò dára ni pé: Òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin ní ìgbéraga. Wọ́n ní oúnjẹ lọpọlọpọ, ara sì rọ̀ wọ́n, ṣugbọn wọn kò ran talaka ati aláìní lọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, ẹ̀ṣẹ Sodomu arabinrin rẹ niyi, irera, onjẹ ajẹyo, ati ọ̀pọlọpọ orayè wà ninu rẹ̀, ati ninu awọn ọmọ rẹ̀ obinrin; bẹ̃ni on kò mu ọwọ́ talaka ati alaini lokun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Wò ó, ẹ̀sẹ̀ tí Sódómù ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin sẹ̀ nìyìí: Òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ gbéraga, wọ́n jẹ́ alájẹjù àti aláìbìkítà; wọn kò ran talákà àti aláìní lọ́wọ́