Ezekiel 16:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹnikẹ́ni kò wò ọ́ lójú, kí ó ṣàánú rẹ, kí ó ṣe ọ̀kan kan ninu àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì fún ọ. Ṣugbọn wọ́n gbé ọ sọ sinu pápá, nítorí pé wọ́n kórìíra rẹ ní ọjọ́ tí wọ́n bí ọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kò si oju ti o kãnu fun ọ, lati ṣe ọkan ninu nkan wọnyi fun ọ, lati ṣe iyọnu si ọ; ṣugbọn ninu igbẹ li a gbe ọ sọ si, fun ikorira ara rẹ, ni ijọ ti a bi ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kò sẹ́ni tó ṣàánú tàbí kẹ́dùn rẹ débi àtiṣe ikankan nínú iwọ́nyi fún ọ ṣùgbọ́n lọ́jọ́ ìbí rẹ, ìta la jù ọ́ sí torí wọ́n kórìíra rẹ.