Ezekiel 16:51 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹ̀ṣẹ̀ tí Samaria dá kò tó ìdajì èyí tí ìwọ dá, ohun ìríra tí o ṣe sì jù tiwọn lọ. O ti mú kí arabinrin rẹ dàbí olódodo lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ, nítorí pé nǹkan ìríra tí o ṣe pọ̀ pupọ ju tirẹ̀ lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni Samaria kò dá abọ̀ ẹ̀ṣẹ rẹ: ṣugbọn iwọ sọ ohun irira rẹ di pupọ jù wọn lọ, o si ti da awọn arabinrin rẹ lare ninu gbogbo ohun irira rẹ ti iwọ ti ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Samaríà kò ṣe ìdájìn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Ìwọ ṣe àwọn ohun ìríra ju tirẹ̀ lọ, ìwọ sì jẹ kí àwọn arabìnrin rẹ dàbí olódodo pẹ̀lú gbogbo ìwọ̀nyí tí ìwọ ti ṣe.