Ezekiel 16:52 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó yẹ kí ojú ti ìwọ pàápàá, nítorí o ti jẹ́ kí ìdájọ́ gbe àwọn arabinrin rẹ, nítorí nǹkan ìríra tí o ṣe ju tiwọn lọ. Ọ̀nà wọn tọ́ ju tìrẹ lọ, nítorí náà, ó yẹ kí ojú tì ọ́, nítorí o ti mú kí àwọn arabinrin rẹ dàbí olódodo lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ pẹlu, ti o ti da awọn arabinrin rẹ lẹbi, ru itiju ara rẹ, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ ti iwọ ti ṣe ni iṣe irira jù wọn lọ: awọn ṣe olododo jù iwọ lọ; nitotọ, ki iwọ ki o dãmu pẹlu, si ru itiju rẹ, nitipe iwọ dá awọn arabinrin rẹ lare.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gba ìtìjú rẹ, nítorí ìwọ ti jẹ́ kí arábìnrin rẹ gba ìdáláre. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ti burú ju tí wọn lọ, wọn dàbí olódodo ju ìwọ lọ. Torí náà rú ìtíjú rẹ, kí o sì gba ẹ̀gàn rẹ pẹ̀lú nítorí ìwọ ti jẹ́ kí àwọn arábìnrin rẹ dàbí olódodo.