Ezekiel 16:53 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA sọ níti Jerusalẹmu pé, “N óo dá ire wọn pada: ire Sodomu ati ti àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin ati ire Samaria ati ti àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin. N óo dá ire tìrẹ náà pada pẹlu tiwọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati mo ba tun mu igbèkun wọn wá, igbèkun Sodomu ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, pẹlu igbèkun Samaria ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, nigbana li emi o tun mu igbèkun awọn onde rẹ wá lãrin wọn:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sódómù àti àwọn ọmọbìnrin rẹ padà ìgbèkùn àti Samaríà pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin rẹ, èmi yóò sì dá ìgbèkùn tirẹ̀ náà padà pẹ̀lú wọn