Ezekiel 16:61 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
O óo wá ranti gbogbo ìwà rẹ, ojú yóo sì tì ọ́ nígbà tí mo bá mú ẹ̀gbọ́n rẹ obinrin ati àbúrò rẹ obinrin, tí mo sì fà wọ́n lé ọ lọ́wọ́ bí ọmọ; ṣugbọn tí kò ní jẹ́ pé torí majẹmu tí mo bá ọ dá ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si ranti ọ̀na rẹ, oju o si tì ọ, nigbati iwọ ba gba awọn arabinrin rẹ, ẹgbọ́n rẹ ati aburò rẹ: emi o si fi wọn fun ọ bi ọmọbinrin, ṣugbọn ki iṣe nipa majẹmu rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ìwọ yóò rántí àwọn ọ̀nà rẹ ojú yóò sì tì ọ́ nígbà tí mo bá gba àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ obìnrin padà: Fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọmọbìnrin, ṣùgbọ́n kì í ṣe lórí májẹ̀mú tí mo bá ọ dá.