Ezekiel 17:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Bi àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọnyi pé, ṣé wọn kò mọ ìtumọ̀ òwe wọnyi ni? Sọ pé ọba Babiloni wá sí Jerusalẹmu, ó sì kó ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ ní Babiloni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sọ nisisiyi fun ọlọ̀tẹ ile na pe, Ẹnyin kò mọ̀ ohun ti nkan wọnyi jasi? Sọ fun wọn, kiyesi i, ọba Babiloni de Jerusalemu, o si ti mu ọba ibẹ ati awọn ọmọ-alade ibẹ, o si mu wọn pẹlu rẹ̀ lọ si Babiloni:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Sọ fún ọlọ̀tẹ̀ ilé yìí, ‘Ǹjẹ́ ẹ mọ ìtumọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí?’ Sọ fún wọn: ‘Ọba a Bábílónì wá sí Jérúsálẹ́mù ó sì kó Ọba àti àwọn ìjòyè ọmọ aládé ibẹ̀ lọ sí Bábílónì lọ́dọ̀ rẹ̀.