Ezekiel 17:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Idà ni wọn óo fi pa àwọn tí wọ́n bá sá lára àwọn ọmọ ogun rẹ̀, a óo sì fọ́n àwọn tí wọ́n bá kù ká sí gbogbo ayé, ẹ óo wá mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo sọ̀rọ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati gbogbo awọn isánsa rẹ̀ pẹlu gbogbo awọn ẹgbẹ́-ogun rẹ̀, ni yio ti oju idà ṣubu; awọn ti o si kù ni a o tuka si gbogbo ẹfũfu: ẹnyin o si mọ̀ pe emi Oluwa li o ti sọ ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ìsáǹsá àti ọ̀wọ́ ọmọ ogun rẹ̀ ni yóò kú pẹ̀lú idà, èmi yóò sì fọn àwọn ìyókù ká sínú afẹ́fẹ́ káàkiri. Nígbà náà ni yóò mọ̀ pé, “Èmi OLÚWA lo sọ̀rọ̀.”