Ezekiel 17:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Idì ńlá mìíràn tún wà, apá rẹ̀ tóbi, ìyẹ́ rẹ̀ sì pọ̀ lọpọlọpọ. Àjàrà yìí bá kọ orí gbòǹgbò ati ẹ̀ka rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ idì ńlá yìí, kí Idì náà lè máa bomi rin ín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Idì nla miran si wà pẹlu apá nla ati iyẹ́ pupọ: si kiye si i, àjara yi tẹ̀ gbòngbo rẹ̀ sọdọ rẹ̀, o si yọ ẹka rẹ̀ sọdọ rẹ̀, ki o le ma b'omi si i ninu aporo ọgbà rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ṣùgbọ́n ẹyẹ Idì ńlá mìíràn tún wá, tó ní apá títóbi pẹ̀lú ìyẹ́ púpọ̀. Gbòǹgbò àjàrà náà sì ta lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti orí ilẹ̀ tí wọn gbìn ín sí, ó wá pẹ̀ka lọ sọ́dọ̀ rẹ kí ó le fún-un ni omi.