Ezekiel 17:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Sọ fún wọn pé, èmi OLUWA Ọlọrun ní kí o bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, ‘Ṣé àjàrà yìí yóo ṣe dáradára? Ṣé idì ti àkọ́kọ́ kò ní fa gbòǹgbò rẹ̀ tu, kí ó gé ẹ̀ka rẹ̀, kí àwọn ewé rẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ sì rọ?’ Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ nílò alágbára tabi ọ̀pọ̀ eniyan, láti fà á tu tigbòǹgbò tigbòǹgbò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wipe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; yio ha gbà? on kì yio hú gbòngbo rẹ̀, kì yio si ka eso rẹ̀ kuro, ki o le rọ? yio rọ ninu gbogbo ewe rirú rẹ̀, ani laisi agbara nla tabi enia pupọ̀ lati fà a tu pẹlu gbòngbo rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí OLÚWA Ọlọ́run wí nìyí: Yóò wá gbilẹ̀ bí? A kò wá ní i wú gbòǹgbò rẹ̀, ki a si gé èso rẹ̀ kúrò kí ó bá à le rọ? Gbogbo ewé rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ ni yóò rẹ̀. Kò sì ní gba agbára tàbí ènìyàn púpọ̀ láti fà gbòngbò rẹ̀ tu.