Ezekiel 18:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
tí ń gba owó èlé; ǹjẹ́ irú eniyan bẹ́ẹ̀ lè yè? Kò lè yè rárá. Nítorí pé ó ti ṣe àwọn ohun ìríra wọnyi, yóo kú ni dájúdájú; lórí ara rẹ̀ sì ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ti o ti fi fun ni lati gba ẹdá, ti o si ti gba èle: on o ha yè bẹ̃? on ki yio yè: on ti ṣe gbogbo ohun irira wọnyi; kikú ni yio kú: ẹjẹ rẹ̀ yio wà lori rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó ń fowó ya ni pẹ̀lú èlé ó sì tún ń gba èlé tó pọ̀jù. Ǹjẹ́ irú ọkunrin yìí wa le è yè bí? Kò lè wá láàyè! Nítorí pé ó ti ṣe àwọn ohun ìríra yìí, yóò kú, ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò sì wá lórí rẹ̀.