Ezekiel 18:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
tí ó yàgò fún ẹ̀ṣẹ̀, tí kì í gba owó èlé, tí ń pa òfin mi mọ́, tí sì ń rìn ninu ìlànà mi, kò ní kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀, dájúdájú yóo yè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ti o ti mu ọwọ́ rẹ̀ kuro lara ẹni-inilara, ti kò ti gba ẹdá tabi elé ti o ti mu idajọ mi ṣẹ, ti o ti rìn ninu aṣẹ mi; on kì yio kú nitori aiṣedẽde baba rẹ̀, yiyè ni yio yè.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó ń yọ ọwọ́ rẹ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀, kò sì gba èlé tàbí èlé tó pọ̀jù, ó ń pa òfin mi mọ́, ó sì ń tẹ̀lé àwọn àsẹ mi. Kò ní kú fún ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀, nítòótọ́ ní yóò yè!