Ezekiel 18:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Sibẹsibẹ ẹ̀ ń sọ pé, ‘Kí ló dé tí ọmọ kò fi ní jìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀?’ Níwọ̀n ìgbà tí ọmọ bá ti ṣe ohun tí ó bá òfin mu, tí ó sì ti mú gbogbo ìlànà mi ṣẹ; dájúdájú yóo yè ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ẹnyin wipe, Ẽṣe? ọmọ kò ha ru aiṣedẽde baba? Nigbati ọmọ ti ṣe eyiti o tọ́ ati eyiti o yẹ, ti o si ti pa gbogbo aṣẹ mi mọ, ti o si ti ṣe wọn, yiyè ni yio yè.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Síbẹ̀, ẹ tún ń bèèrè pé, ‘Kí ló dé ti ọmọ kò ní í ru ẹ̀bi baba rẹ̀?’ Níwọ̀n ìgbà tí ọmọ ti ṣe ohun tó tọ́, tó sì yẹ, tó sì ti kíyè sí ara láti pa gbogbo àṣẹ mi mọ́, nítòótọ́ ni pé yóò yè.