Ezekiel 18:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ṣugbọn bí eniyan burúkú bá yipada kúrò ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń dá, tí ó ń pa òfin mi mọ́, tí ó ń ṣe ohun tí ó tọ́, tí ó sì bá òfin mu, dájúdájú yóo yè ni, kò ní kú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi enia buburu yio ba yipada kuro ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti da, ti o si pa gbogbo aṣẹ mi mọ, ti o si ṣe eyi ti o tọ́, ati eyiti o yẹ, yiyè ni yio yè, on kì yio kú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣùgbọ́n bí ènìyàn búburú bá yípadà kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tó ti dá, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa àsẹ mi mọ́, tó sì ń ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó yẹ, nítòótọ́ ni yóò yè, kò sì ní kú.