Ezekiel 18:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nítorí náà, n óo da yín lẹ́jọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Ìwà olukuluku ni n óo fi dá a lẹ́jọ́. Ẹ ronupiwada, kí ẹ sì yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ̀ṣẹ̀ má baà pa yín run. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina emi o dá nyin lẹjọ, ile Israeli, olukuluku gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀, ni Oluwa Ọlọrun wi. Ẹ yipada, ki ẹ si yi kuro ninu gbogbo irekọja nyin; bẹ̃ni aiṣedẽde kì yio jẹ iparun nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà, ilé Ísírẹ́lì, n ó da yín lẹ́jọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ẹnì kọ̀ọ̀kan yín bá ṣe rí ni OLÚWA Ọlọ́run wí. Yípadà! Kí ẹ si yí kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ̀ṣẹ̀ ma ba a jẹ́ ọ̀nà ìsubú yín.