Ezekiel 18:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
bí kò bá bá wọn jẹ ẹbọ lórí àwọn òkè, tabi kí ó bọ àwọn oriṣa ilé Israẹli; tí kò bá bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀, tabi kí ó bá obinrin lòpọ̀ ní àkókò tí ó ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ lọ́wọ́;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ti kò si jẹun lori oke, ti kò si gbe oju rẹ̀ soke si awọn oriṣa ile Israeli, ti kò si bà obinrin aladugbo rẹ̀ jẹ, ti kò sì sunmọ obinrin ti o wà ninu aimọ́ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
tí kò bá wọn jẹun lórí òkè gíga, tí kò gbójú rẹ̀ sókè sí àwọn òrìṣà ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ti kò sì bá obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́ tàbí kí ó sùn ti obìnrin ni àsìkò èérí rẹ̀.