Ezekiel 19:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn a fa àjàrà náà tu pẹlu ibinu, a sì jù ú sílẹ̀. Afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn mú kí ó gbẹ, gbogbo èso rẹ̀ sì rẹ̀ dànù. Igi rẹ̀ tí ó lágbára gbẹ, iná sì jó o.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn a fã a tu ni irúnu, a wọ ọ lulẹ, ẹfũfu ila-õrun si gbe eso rẹ̀, ọpá lile rẹ̀ ti ṣẹ, o si rọ; iná jo o run.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n a hú àjàrà yìí pẹ̀lú ìbínú, á sì wo o lulẹ̀, afẹ́fẹ́ láti ìlà oorùn sì mú koko, wọ́n sọ ọ́ di aláìléso, àwọn ẹka rẹ̀ tó lágbára tẹ́lẹ̀ sì rọ wọ́n sì jó wọn.