Ezekiel 19:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Iná ṣẹ́ lára igi rẹ̀, ó sì jó gbogbo ẹ̀ka ati èso rẹ̀. Kò sì ní igi tí ó lágbára mọ́, tí a lè fi gbẹ́ ọ̀pá àṣẹ fún ọba. Dájúdájú ọ̀rọ̀ arò ni ọ̀rọ̀ yìí, ó sì ti di orin arò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iná si jade lati inu ọpá kan ninu ẹka rẹ̀, ti o ti jo eso rẹ̀ run, tobẹ̃ ti kò fi ni ẹka ti o le lati ṣe ọpa lati joye. Eyi ni ohùnrére ẹkun, yio si jẹ ohùn-rére ẹkun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Iná sì jáde láti ọ̀kan lára ẹ̀ka rẹ̀ ó sì pa ẹ̀ka àti èso rẹ̀ run, débi pé kò sí ẹ̀ka tó lágbára lórí rẹ̀ mọ́; èyí to ṣe e fi ṣe ọ̀pá fún olórí mọ́.’ Èyí ni orin ọ̀fọ̀ a o sì máa lo bí orin ọ̀fọ̀.”